ỌỌ̀NI KÒ ṢE RÍFÍN- Daniel Adefare
ỌỌ̀NI KÒ ṢE RÍFÍN. Apá kìíní lati ọwọ́ Daniel Adefare Oríadé, ọrùn-ìlẹ̀kẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ajunilọ mo júbà o. Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní "Kíkéré labẹ́rẹ́ kéré, kìí ṣe mímì fádìyẹ" Káláyé tó dáyé, kékeré kọ́ ni Bàbá fi ju ọmọ lọ. Ọọ̀ni kìí ṣe ẹgbẹ́ ọba kọ́ba gẹ́gẹ́ ìtàn ti sọ́ ọ di mímọ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́ ? Eégún ilé kò ṣe rífín, òòṣà ọjà kò ṣe é gbálójú bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Ọba Ẹnìtàn Adéyẹyè Ògúnwùsì, Ọọ̀ni tilẹ̀ Ifẹ̀ ri. Ẹni tó bá fi ojú di Ọọ̀ni, dandan ni kí àwówó wó. Eyín funfun báláí ni iyì ẹnu, ẹ̀jẹ̀ pupa yòò ni iyì òòṣà, àpọ́nlé ló yẹ olórí Ọba yoòbá gbogbo kìí ṣe ìwọ̀sí. Ohun ti Ọba Rílíwànù Akiolú, Ọba Èèkó ṣe sí Ọọ̀ni kò dara rárá. A kò lè rìn kórí má mì nítòótọ́, orí bíbẹ́ kọ́ ni oògùn orí fífọ́ kẹ̀! Ó wu èdùmàrè ló gbórí ẹwà fún àkùkọ, ọ̀pọ̀ igi ló ń bẹ nígbó ká tó fí ìrókò jọba igi. Ẹ máa jẹ kí á torí ọ̀làjú tàbí òṣèlú gbàgbé àṣà wa. Àṣà ìbọ̀wọ̀ fágbà ni Yorùbá fi ń gbajúmọ̀ nílẹ̀-kílẹ̀. Àgbà kò ní ṣe pẹ̀lú ọjọ́-orí rárá, ipò làgbà. Àràbà ni bàbá, ẹni a bá lábà ni bàbá...