ỌỌ̀NI KÒ ṢE RÍFÍN- Daniel Adefare


ỌỌ̀NI KÒ ṢE RÍFÍN. Apá kìíní lati ọwọ́ Daniel Adefare Oríadé, ọrùn-ìlẹ̀kẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ajunilọ mo júbà o. Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní "Kíkéré labẹ́rẹ́ kéré, kìí ṣe mímì fádìyẹ" Káláyé tó dáyé, kékeré kọ́ ni Bàbá fi ju ọmọ lọ. Ọọ̀ni kìí ṣe ẹgbẹ́ ọba kọ́ba gẹ́gẹ́ ìtàn ti sọ́ ọ di mímọ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́ ? Eégún ilé kò ṣe rífín, òòṣà ọjà kò ṣe é gbálójú bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Ọba Ẹnìtàn Adéyẹyè Ògúnwùsì, Ọọ̀ni tilẹ̀ Ifẹ̀ ri. Ẹni tó bá fi ojú di Ọọ̀ni, dandan ni kí àwówó wó. Eyín funfun báláí ni iyì ẹnu, ẹ̀jẹ̀ pupa yòò ni iyì òòṣà, àpọ́nlé ló yẹ olórí Ọba yoòbá gbogbo kìí ṣe ìwọ̀sí. Ohun ti Ọba Rílíwànù Akiolú, Ọba Èèkó ṣe sí Ọọ̀ni kò dara rárá. A kò lè rìn kórí má mì nítòótọ́, orí bíbẹ́ kọ́ ni oògùn orí fífọ́ kẹ̀! Ó wu èdùmàrè ló gbórí ẹwà fún àkùkọ, ọ̀pọ̀ igi ló ń bẹ nígbó ká tó fí ìrókò jọba igi. Ẹ máa jẹ kí á torí ọ̀làjú tàbí òṣèlú gbàgbé àṣà wa. Àṣà ìbọ̀wọ̀ fágbà ni Yorùbá fi ń gbajúmọ̀ nílẹ̀-kílẹ̀. Àgbà kò ní ṣe pẹ̀lú ọjọ́-orí rárá, ipò làgbà. Àràbà ni bàbá, ẹni a bá lábà ni bàbá. Ọba Adéyeyè lè jẹ́ ọmọdé sùgbọ́n ipò àti àyè tí ó wà gẹ́gẹ́ bí i ỌỌ̀NI ti sọ ọ́ di àràbà tí gbogbo ọba bá lábà. Bí èèyàn bá ta ará ilé ẹ̀ lọ́pọ̀, kò le rí i rà lọ́wọ̀ń. Bàbá ni Ọọ̀ní jẹ́ láàárín àwọn lọ́ba-lọ́ba. Níwọ̀n ìgbà tí àwọn Ọba tí kìí ṣe Ọba ní ilẹ̀ káàárọ̀-o-jíire lè máa ṣe àpọ́nlé tí ó tọ́ fún Ọọ̀ni, mo lérò pé ó tọ́, ó sì yẹ kí àwọn Ọba yorùbá ṣe àpọ́nlé ara wọn bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ,pàápàá jùlọ fún olórí aládé gbogbo. Mo kí Ọba Adéyẹyè Ẹnitan Ògúnwùsì, Ọ̀jájá II, kú àíbínú. N kò sàì gbóríyìn fún gbgbo ẹni tó da sí ọ̀rọ̀ náà ní pàtàkì jùlọ Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ GCFR, ààrẹ àná. Mo rọ́ Ọba Èèko ki ó máa bínú sí Ọọ̀ni lórí ohun tí ó lè fa ìwà àjòjì yìí. Àmọ̀nràn mi ni pé kí Ọba Akiolú ti Èèkó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ọ Ọọ̀ni àti gbogbo ọmọ yorùbá pé òun kò ní dárú asọ bẹ́ẹ̀ sorò mọ. Lákòtán ọ̀rọ̀ mi, Baba kìí bínú púpọ̀, Kábíèsí, ọba Adéyẹyẹ̀ ẹ fojú fo, bẹ́ẹ̀ ni, ẹ máa gbàgbé ọ̀rọ̀ àwọn Baba ńlá yín pé "Iṣu ẹni níi tọwọ́ ẹnị bepo" kí òwe jẹ́ ti ẹ̀yin àgbà. Kí ẹsin ọba kó joko pẹ́. Ilẹ̀ yorùbá kò ní dàrú o. Àṣẹ. Tóò bí ó ti mọ ní í jẹ ìrẹ́mọ. Ẹ jẹ kí ẹyin mi di àkùkọ. Ẹ ṣé púpọ̀. Ọgbẹ́ni Daniel Adefare 08033234826

Comments

Popular posts from this blog

OONI RECEIVES SON, PRINCE ADESOJI ADEREMI, RELEASES FACIAL IDENTITY TO THE PUBLICThe Ooni of Ife & Arole Oodua, Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja II, on Tuesday received his crown prince Tadenikawo Adesoji Aderemi Ogunwusi, releasing his pictures to the public. The Prince came in a motorcade to the entrance(Enu Geru)of the Palace and received by the AGBA IFE led by Obalufe of Ife, Oba Idowu Adediwura, The MODEWA led by Lowa Adimula of Ife, Highchief Adeola Adeyeye and EMESEs led by Sarun Oriowo Oyeyemi. They all ushered the Prince and his mother, Queen ShilekunOla Ogunwusi(YEYELUWA), the families, friends and associates from Akure into the Ooni's Palace.The Prince and his mother first stopped at Ile-Nla within the palace courtyard where the families and relatives of Ogunwusi Royal families and friends were awaiting the arrival of the baby from where they proceeded to Emese's court, where the Prince was finally handed over to his joyful father, Ooni Adeyeye Ogunwusi who came out through the sacred ILE IGBO in accordance to the full culture and traditions of Ile-Ife as always observed whenever a reigning Ooni receives his newly born Prince into the palace after the necessary rites of 21 days.After receiving his son from the mother, Ooni Ogunwusi accompanied by relevant spiritual aides swiftly took the baby straight into the inner chamber of ILE IGBO for the necessary spiritual confirmation to establish the blood lineage of Oduduwa our progenitor following the foots steps of his ancestors. The monarch later came out from ILE IGBO with smiles and majestic dance steps welcomed by thunderous shouts "Kabiyesi ooooo!" "Kabiyesi oooooo!" from the waiting crowd who watched with excitements and jubilations as Ooni handed over the Prince to his elated mother who danced with the baby in her hands to her apartment at the palace. Ooni's Palace was full of activities as various people across the country came in droves to witness the grand entry of the Prince and the subsequent handing over to the joyous father who was seeing him for the first time since he was born 3 weeks ago.It would be recalled that the palace of the Ooni of Ife two weeks ago during the 8 day naming ceremony announced that it would not release the facial identity of the Prince to the public until after the mandated 21 days in line with the cultural legacy established by Oduduwa Olofin Adimula several centuries ago.Signed;Comrade Moses Olafare,Director, Media & Public Affairs,Ooni's Palace.